ATELEWO

in #nigeria7 years ago

Ọwọ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà ara ti ènìyàn ni. O jẹ eya ara ti o wúlò púpò, tí eniyan máa nlo láti fi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣe bíi gbígbé ẹrú, wiwe iwe, fifo nkan àti bẹẹbẹẹ lọ.

Lára ọwọ ni atelewo wa, èyí tí ó máa ń rán ni lowo nigbakugba tí a bá fẹ́ jẹun tàbí fò nkan. Atelewo wúlò lọ́nà tó pò nígbà tí a bá fẹ́ sise. Ìdí nìyí tí àwọn àgbàlagbà fi npa lowe pé atelewo ẹni kii tán ni jẹ.

Ní atelewo kọ̀ọ̀kan ni ila wá, èyí tí kò sì ẹni tí ó lè sọ bí ó ṣe de ibè. Abájọ tí àwọn bàbá wa se maa n sọ wipe atewo ni mo ba ìlà, mi ò mọ ẹni tí ó kó ọ. Ilá yìí tí ó ń bẹ lowo olúkúlùkù ènìyàn yàtọ̀ sí ara wọn. Tí Taiwo yàtọ̀ sí ti Kehinde, tí Idowu kò jọ tí Alaba. Bí ó ti wù ki ènìyàn ó jọra tó, ilá ọwọ wá yóò yàtọ̀.

Ila tí ó ń bẹ lowo ènìyàn yìí ni àwọn kan gbagbọ pé ó ń sọ nípa ohun tí eniyan yoo da láyé. Ní ayé àtijọ́, a máa ń wo akosejayé ọmọ tí a bí nípa yíyẹ ọwọ wọn wò. Bákan náà àwọn tí wọn máa nlo ṣe ayẹwo lọdọ babalawo, a má ṣe alabapade irú nkan báyìí. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn agbofinro a máa lo ilá ọwọ láti mọ ẹni tí ó dà ọ̀ràn kan tàbí òmíràn. Àwọn pàtàkì ìlà owo wá niyii.

Èyí tí ó wù kí ó lè rí di mú nínú nkan wonyii, mo dájú pé Ọlọ́run dá ọ láti lọ owó rẹ fún nkan rere ní. Mase fi ọwọ rẹ ṣe ohun búburú tàbí hu ìwà ìkà. Mo dájú wípé ohun tí eniyan ba fúnrúgbìn ni yóò ká. Bákan náà, rántí wípé atelewo ẹni kii tán ni je. Gbìyànjú láti wá ohun kan ń fi ọwọ rẹ ṣe. Tí ó bá jẹ ẹni tí ó mọ nkan ko bí irú anfaani tí steemit yìí, lo ó daradara láti kó ohun tí yóò yí ẹlòmíràn lọ́kàn padà tàbí tún ayé wọn ṣe.

Lo ọwọ rẹ daradara. IMG-20180126-WA0008.jpg

Sort:  

Looks cool, the more you practice you more perfect it becomes.

What a post! Keep it up.

Thank you. Really appreciate it.

Owo je eya ara ti o se pataki
Nice post boss